Kronika Keji 17 BM

Jehoṣafati di Ọba

1 Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbáradì láti dojú ìjà kọ Israẹli.

2 Ó kó àwọn ọmọ ogun sí gbogbo àwọn ìlú olódi Juda, ó yan olórí ogun fún wọn ní ilẹ̀ Juda ati ní ilẹ̀ Efuraimu tí Asa baba rẹ̀ gbà.

3 OLUWA wà pẹlu Jehoṣafati nítorí pé ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbà ọ̀dọ̀ Dafidi, baba rẹ̀; kò sì bọ oriṣa Baali.

4 Ṣugbọn ó ń sin Ọlọrun àwọn baba rẹ̀, ó pa òfin Ọlọrun mọ́, kò sì tẹ̀lé ìṣe àwọn ọmọ Israẹli.

5 Nítorí náà OLUWA fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ Juda sì ń san owó orí fún un. Nítorí náà ó di ọlọ́rọ̀ ati ọlọ́lá.

6 Ó fi ìgboyà rìn ní ọ̀nà OLUWA, ó wó gbogbo pẹpẹ oriṣa, ó sì gé àwọn ère Aṣera káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda.

7 Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó pe àwọn marun-un ninu àwọn ìjòyè rẹ̀: Benhaili, Ọbadaya, ati Sakaraya, Netaneli, ati Mikaya, ó rán wọn jáde láti máa kọ́ àwọn eniyan ní ilẹ̀ Juda.

8 Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wọn lọ ni: Ṣemaaya, Netanaya, ati Sebadaya; Asaheli, Ṣemiramotu, ati Jehonatani; Adonija, Tobija ati Tobadonija. Àwọn alufaa tí wọ́n tẹ̀lé wọn ni Eliṣama ati Jehoramu.

9 Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda pẹlu ìwé òfin lọ́wọ́ wọn, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan.

Títóbi Jehoṣafati

10 OLUWA da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí Juda ká, wọn kò sì gbógun ti Jehoṣafati.

11 Àwọn kan ninu àwọn ará Filistia mú ẹ̀bùn ati fadaka wá fún Jehoṣafati gẹ́gẹ́ bíi ìṣákọ́lẹ̀. Àwọn ará Arabia náà sì mú ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) àgbò, ati ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) òbúkọ wá.

12 Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i, ó kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ ati àwọn ìlú tí wọn ń kó ìṣúra pamọ́ sí ní Juda;

13 ó ní ilé tí wọn ń kó nǹkan pamọ́ sí ní àwọn ìlú ńláńlá Juda.Ó sì ní àwọn akọni ọmọ ogun ní Jerusalẹmu.

14 Iye àwọn ọmọ ogun tí ó kó jọ nìyí gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: Adinai ni olórí ogun ẹ̀yà Juda, ó sì ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọmọ ogun lábẹ́ rẹ̀.

15 Olórí ogun tí ó pọwọ́ lé e ni Jehohanani, ó ní ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) ọmọ ogun lábẹ́ rẹ̀.

16 Olórí ogun kẹta ni Amasaya, ọmọ Sikiri, ẹni tí ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ OLUWA, ó ní ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) akọni ọmọ ogun.

17 Àwọn olórí ogun láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini ni: Eliada, akọni ọmọ ogun, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń lo apata ati ọrun ni wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀.

18 Igbákejì ni Jehosabadi; òun náà ní ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) ọmọ ogun tí wọ́n ti dira ogun, lábẹ́ rẹ̀.

19 Gbogbo àwọn wọnyi ni wọ́n wà lábẹ́ ọba ní Jerusalẹmu, láìka àwọn tí ó fi sí àwọn ìlú olódi ní gbogbo ilẹ̀ Juda.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36