Kronika Keji 29 BM

Hesekaya, Ọba Juda

1 Hesekaya jọba ní Juda nígbà tí ó di ẹni ọdún mẹẹdọgbọn; ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abija, ọmọ Sakaraya.

2 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.

Yíya Tẹmpili sí Mímọ́

3 Ní oṣù kinni ọdún kinni ìjọba rẹ̀, ó ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ó sì tún wọn ṣe.

4 Ó kó àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ sí gbàgede tí ó wà ní apá ìlà oòrùn ilé Ọlọrun.

5 Ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Lefi, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì ya ilé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín sí mímọ́ pẹlu. Ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan ẹ̀gbin kúrò ninu ibi mímọ́,

6 nítorí àwọn baba wa ti ṣe aiṣododo, wọ́n sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, Ọlọrun wa. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n gbójú kúrò lára ibùgbé rẹ̀, wọ́n sì kẹ̀yìn sí i.

7 Wọ́n ti ìlẹ̀kùn yàrá àbáwọlé tẹmpili, wọ́n pa fìtílà tí ó wà ní ibi mímọ́, wọn kò sun turari, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rú ẹbọ sísun ní ibi mímọ́ sí Ọlọrun Israẹli.

8 Nítorí náà ni OLUWA ṣe bínú sí Juda ati Jerusalẹmu, ohun tí Ọlọrun fi wọ́n ṣe sì dẹ́rùba gbogbo eniyan. Wọ́n di ẹni ẹ̀gàn ati ẹni àrípòṣé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i lónìí.

9 Ìdí nìyí tí àwọn baba wa fi ṣubú lójú ogun tí wọ́n sì kó àwọn ọmọ ati àwọn aya wa lẹ́rú.

10 “Nisinsinyii, mo ti pinnu láti bá OLUWA Ọlọrun Israẹli dá majẹmu, kí ibinu gbígbóná rẹ̀ lè kúrò lórí wa.

11 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má jáfara, nítorí pé OLUWA ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀, ati láti sìn ín; láti jẹ́ iranṣẹ rẹ̀ ati láti máa sun turari sí i.”

12 Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe ní tẹmpili nìwọ̀nyí: láti inú ìdílé Kohati: Mahati, ọmọ Amasai, ati Joẹli, ọmọ Asaraya; láti inú ìdílé Merari: Kiṣi, ọmọ Abidi ati Asaraya, ọmọ Jahaleleli; láti inú ìdílé Geriṣoni: Joa, ọmọ Sima ati Edẹni, ọmọ Joa.

13 Láti inú ìdílé Elisafani: Ṣimiri ati Jeueli; láti inú ìdílé Asafu: Sakaraya ati Matanaya,

14 láti inú ìdílé Hemani: Jeueli ati Ṣimei; láti inú ìdílé Jedutuni: Ṣemaaya ati Usieli.

15 Wọ́n bá kó àwọn arakunrin wọn jọ, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́. Wọ́n wọ ilé OLUWA láti tọ́jú rẹ̀ bí ọba ti pa á láṣẹ, gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.

16 Àwọn alufaa wọ ibi mímọ́ lọ láti tọ́jú rẹ̀. Gbogbo ohun aláìmọ́ tí wọ́n rí ninu tẹmpili OLUWA ni wọ́n kó sí àgbàlá ilé náà. Àwọn ọmọ Lefi sì kó gbogbo wọn lọ dà sí odò Kidironi lẹ́yìn ìlú.

17 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sí mímọ́ ní ọjọ́ kinni oṣù kinni. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá sí yàrá àbáwọlé ilé OLUWA. Ọjọ́ mẹjọ ni wọ́n fi ya ilé OLUWA sí mímọ́, wọ́n parí ní ọjọ́ kẹrindinlogun oṣù náà.

A Tún Tẹmpili Yà sí Mímọ́

18 Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ Hesekaya ọba lọ, wọ́n sọ fún un pé, “A ti tọ́jú ilé OLUWA: ati pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo ohun èlò rẹ̀, ati tabili àkàrà ìfihàn ati gbogbo ohun èlò rẹ̀.

19 Gbogbo àwọn ohun èlò tí Ahasi ọba ti patì nígbà tí ó ṣe aiṣododo ni a ti tọ́jú, tí a sì ti yà sí mímọ́. A ti kó gbogbo wọn siwaju pẹpẹ OLUWA.”

20 Hesekaya ọba dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó kó gbogbo àwọn ìjòyè ìlú jọ, wọ́n bá lọ sinu ilé OLUWA.

21 Wọ́n fi akọ mààlúù meje, àgbò meje, ọ̀dọ́ aguntan meje ati òbúkọ meje rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba Hesekaya, ati ilé OLUWA ati ilé Juda. Ọba pàṣẹ pé kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni, fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA.

22 Àwọn akọ mààlúù ni wọ́n kọ́kọ́ pa, àwọn alufaa gba ẹ̀jẹ̀ wọn, wọ́n dà á sára pẹpẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n pa àwọn àgbò, wọ́n sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sára pẹpẹ.

23 Lẹ́yìn náà wọ́n kó àwọn òbúkọ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wá sọ́dọ̀ ọba ati ìjọ eniyan, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn lórí.

24 Àwọn alufaa pa àwọn òbúkọ náà, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn rúbọ lórí pẹpẹ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ọmọ Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ pé wọ́n gbọdọ̀ rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo eniyan.

25 Ọba pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Lefi dúró ninu ilé OLUWA pẹlu ohun èlò orin bíi kimbali, hapu ati dùùrù, gẹ́gẹ́ bí i àṣẹ tí OLUWA pa, láti ẹnu Dafidi ati wolii Gadi tí í ṣe aríran ọba, ati wolii Natani.

26 Àwọn ọmọ Lefi dúró pẹlu ohun èlò orin Dafidi, àwọn alufaa sì dúró pẹlu fèrè.

27 Hesekaya pàṣẹ pé kí wọ́n rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ náà, àwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí kọrin sí OLUWA pẹlu fèrè ati àwọn ohun èlò orin Dafidi, ọba Israẹli.

28 Ọba ati ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí sin OLUWA, àwọn akọrin ń kọrin, àwọn afunfèrè ń fun fèrè títí tí ẹbọ sísun náà fi parí.

29 Nígbà tí wọ́n rú ẹbọ sísun tán, ọba ati ìjọ eniyan wólẹ̀, wọ́n sin Ọlọrun.

30 Ọba ati àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n kọ orin ìyìn Dafidi ati ti Asafu, aríran. Wọ́n fi ayọ̀ kọ orin ìyìn náà, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.

31 Hesekaya bá sọ fún wọn pé: “Nisinsinyii tí ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ wá, kí ẹ sì mú ọrẹ ati ẹbọ ọpẹ́ wá sí ilé OLUWA.” Ìjọ eniyan sì mú ọrẹ ati ẹbọ ọpẹ́ wá, àwọn tí wọ́n fẹ́ sì mú ẹbọ sísun wá.

32 Àwọn nǹkan tí wọn mú wá jẹ́ aadọrin akọ mààlúù, ọgọrun-un (100) àgbò, igba (200) ọ̀dọ́ aguntan, gbogbo rẹ̀ wà fún ẹbọ sísun sí OLUWA.

33 Àwọn ẹran tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ẹbọ jẹ́ ẹgbẹta (600) akọ mààlúù, ati ẹgbẹẹdogun (3,000) aguntan.

34 Àwọn alufaa kò pọ̀ tó láti pa gbogbo ẹran náà, nítorí náà, kí ó tó di pé àwọn alufaa mìíràn yóo ya ara wọn sí mímọ́, àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Lefi, ràn wọ́n lọ́wọ́ títí iṣẹ́ náà fi parí. Àwọn ọmọ Lefi ṣe olóòótọ́ ní yíya ara wọn sí mímọ́ ju àwọn alufaa lọ.

35 Yàtọ̀ sí ọpọlọpọ ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀rá rú ẹbọ alaafia ati ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun.Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ìsìn ninu ilé OLUWA ṣe tún bẹ̀rẹ̀.

36 Hesekaya ati ìjọ eniyan yọ̀ nítorí ohun tí Ọlọrun ṣe fún wọn, nítorí láìròtẹ́lẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36