1 Ọmọ ọdún mẹjọ ni Josaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanlelọgbọn.
2 Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA. Ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dafidi, baba ńlá rẹ̀, nípa títẹ̀lé òfin Ọlọrun fínnífínní.
3 Ní ọdún kẹjọ tí Josaya gorí oyè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọde ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí sin Ọlọrun Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Ní ọdún kejila, ó bẹ̀rẹ̀ sí wó àwọn pẹpẹ oriṣa ní gbogbo ilẹ̀ Juda ati Jerusalẹmu. Ó wó àwọn òpó oriṣa Aṣera, ó sì fọ́ àwọn ère gbígbẹ́ ati èyí tí wọ́n rọ.
4 Wọ́n wó àwọn oriṣa Baali lulẹ̀ níwájú rẹ̀; ó fọ́ àwọn pẹpẹ turari tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó wó àwọn òpó oriṣa Aṣera ati gbogbo àwọn ère tí wọ́n fi igi gbẹ́ ati àwọn tí wọ́n fi irin rọ. Ó fọ́ wọn túútúú, ó sì fọ́n wọn ká sórí ibojì àwọn tí wọn ń sìn wọ́n.
5 Ó sun egungun àwọn babalóòṣà lórí pẹpẹ oriṣa wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fọ Jerusalẹmu ati Juda mọ́ tónítóní.
6 Bákan náà ni ó ṣe ní àwọn ìlú Manase, ati ti Efuraimu, ati àwọn ìlú ilẹ̀ Simeoni títí dé ilẹ̀ Nafutali, ati ní gbogbo àyíká wọn.
7 Ó wó àwọn pẹpẹ, ó lọ àwọn òpó Aṣera ati àwọn ère oriṣa lúúlúú, ó sì wó gbogbo pẹpẹ turari jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Lẹ́yìn náà ó pada sí Jerusalẹmu.
8 Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya, lẹ́yìn tí ó ti pa ìbọ̀rìṣà rẹ́ ní ilẹ̀ náà, ó rán Ṣafani ọmọ Asalaya láti tún ilé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ ṣe pẹlu Maaseaya, gomina ìlú, ati Joa, ọmọ Joahasi tí ó jẹ́ alákòóso ìwé ìrántí.
9 Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Hilikaya, olórí alufaa, wọ́n kó owó tí àwọn eniyan mú wá sí ilé OLUWA fún un, tí àwọn Lefi tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà gbà lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Manase, ati Efuraimu ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yòókù, ati lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń gbé Juda, Bẹnjamini ati Jerusalẹmu.
10 Wọ́n kó owó náà fún àwọn tí ń ṣe àbojútó iṣẹ́ náà. Àwọn ni wọ́n ń sanwó fún àwọn tí wọn ń tún ilé OLUWA ṣe.
11 Wọ́n sanwó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn tí wọn ń mọlé, láti ra òkúta gbígbẹ́ ati pákó ati igi, kí wọ́n fi tún àwọn ilé tí àwọn ọba Juda ti sọ di àlàpà kọ́.
12 Àwọn eniyan náà fi òtítọ́ inú ṣe iṣẹ́ náà. Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣàkóso wọn ni: Jahati ati Ọbadaya, láti inú ìran Merari, ati Sakaraya ati Meṣulamu, láti inú ìran Kohati. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n mọ̀ nípa ohun èlò orin
13 ni wọ́n ń ṣàkóso àwọn tí wọn ń ru ẹrù, ati àwọn tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ mìíràn. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi jẹ́ akọ̀wé, àwọn kan wà nídìí ètò ìsìn, àwọn mìíràn sì jẹ́ aṣọ́nà.
14 Nígbà tí wọn ń kó owó tí àwọn eniyan ti mú wá sinu ilé OLUWA jáde, Hilikaya, alufaa rí ìwé òfin OLUWA tí Ọlọrun fún Mose.
15 Hilikaya sọ fún Ṣafani akọ̀wé, ó ní, “Mo rí ìwé òfin ninu ilé OLUWA.” Ó fún Ṣafani ní ìwé náà,
16 Ṣafani sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba, ó ní, “Àwọn iranṣẹ ń ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ.
17 Wọ́n ti kó owó tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA jọ, wọ́n sì ti kó o fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso iṣẹ́ náà ati àwọn òṣìṣẹ́;”
18 ati pé, “Hilikaya, alufaa, fún mi ní ìwé kan.” Ṣafani sì kà á níwájú ọba.
19 Nígbà tí ọba gbọ́ ohun tí ó wà ninu ìwé òfin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbẹ̀rù ati ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.
20 Ó pàṣẹ fún Hilikaya, Ahikamu, ọmọ Ṣafani, Abidoni, ọmọ Mika, ati Ṣafani, akọ̀wé, ati Asaya, iranṣẹ ọba, pé,
21 “Ẹ tọ Ọlọrun lọ fún èmi ati àwọn eniyan tí wọ́n kù ní Juda ati ní Israẹli, ẹ ṣe ìwádìí ohun tí a kọ sinu ìwé náà; nítorí pé àwọn baba ńlá wa tàpá sí ọ̀rọ̀ OLUWA, wọn kò sì ṣe ohun tí a kọ sinu ìwé yìí ni OLUWA ṣe bínú sí wa lọpọlọpọ.”
22 Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, Hilikaya ati àwọn tí wọ́n tẹ̀lé e, lọ sọ́dọ̀ Hulida, wolii obinrin, iyawo Ṣalumu, ọmọ Tokihati, ọmọ Hasira tí ó jẹ́ alabojuto ibi tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí ní ìhà keji Jerusalẹmu tí Hulida ń gbé. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un.
23 Ó bá dá wọn lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n sọ fun yín, kí ẹ sọ fún ẹni tí ó ran yín sí mi pé
24 òun OLUWA ní òun óo mú ibi wá sórí ibí yìí ati àwọn eniyan ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí a kà sí ọba Juda létí.
25 Nítorí pé wọ́n ti kọ òun OLUWA sílẹ̀, wọ́n sì ń sun turari sí àwọn oriṣa, kí wọ́n lè fi ìṣe wọn mú òun bínú; nítorí náà òun óo bínú sí ibí yìí, kò sí ẹni tí yóo lè dá ibinu òun dúró.
26 Ó ní kí ẹ sọ ohun tí ẹ ti gbọ́ fún ọba Juda tí ó ranṣẹ láti wá wádìí lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní,
27 nítorí pé nígbà tí ó gbọ́ nípa ìyà tí n óo fi jẹ Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀, ó ronupiwada, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi, mo sì ti gbọ́ adura rẹ̀.
28 Nítorí náà, ìdájọ́ tí mo ti pinnu sórí Jerusalẹmu kò ní ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ayé rẹ̀, ikú wọ́ọ́rọ́ ni yóo sì kú.”Àwọn eniyan náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba.
29 Lẹ́yìn náà, Josaya ọba ranṣẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà Juda ati ti Jerusalẹmu.
30 Ó bá lọ sí ilé OLUWA pẹlu gbogbo ará Juda, ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu; ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi ati àwọn eniyan yòókù; ati olówó ati talaka. Ọba ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn.
31 Ó dúró ní ààyè rẹ̀, ó sì bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa fi tọkàntọkàn rìn ní ọ̀nà OLUWA, òun óo máa pa òfin rẹ̀ mọ́, òun óo máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ, òun ó sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. Ó ní òun ó máa fi tọkàntọkàn pa majẹmu tí a kọ sinu ìwé náà mọ́.
32 Lẹ́yìn náà, ó ní kí àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ati àwọn ará Jerusalẹmu bá OLUWA dá majẹmu kí wọ́n sì pa á mọ́. Àwọn ará Jerusalẹmu sì pa majẹmu OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn mọ́.
33 Josaya run gbogbo àwọn ère oriṣa tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, ó sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli sin OLUWA Ọlọrun wọn. Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, wọn kò yipada kúrò lẹ́yìn OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.