Kronika Keji 20 BM

Wọ́n Gbógun ti Edomu

1 Lẹ́yìn èyí, àwọn ará Moabu, ati àwọn ará Amoni, ati díẹ̀ ninu àwọn ará Meuni kó ara wọn jọ láti bá Jehoṣafati jagun.

2 Àwọn kan wá sọ fún Jehoṣafati pé ogun ńlá kan ń bọ̀ wá jà á láti Edomu ní òdìkejì òkun. Wọ́n sọ pé àwọn ọ̀tá náà ti dé Hasasoni Tamari, (tí a tún ń pè ní Engedi).

3 Ẹ̀rù ba Jehoṣafati gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ojú OLUWA, ó kéde jákèjádò ilẹ̀ Juda pé kí wọ́n gbààwẹ̀.

4 Àwọn eniyan péjọ láti gbogbo ìlú Juda, wọ́n wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ OLUWA.

5 Jehoṣafati bá dìde dúró láàrin àwọn tí wọ́n ti Juda ati Jerusalẹmu wá sinu tẹmpili, níbi tí wọ́n péjọ sí níwájú gbọ̀ngàn tuntun,

6 ó ní, “OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọrun ọ̀run. Ìwọ ni o ni àkóso ìjọba gbogbo orílẹ̀-èdè. Agbára ati ipá wà ní ìkáwọ́ rẹ, kò sì sí ẹni tí ó tó dojú kọ ọ́.

7 Ṣebí ìwọ, Ọlọrun wa, ni o lé gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ kúrò fún àwa ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, tí o sì fi ilẹ̀ náà fún arọmọdọmọ Abrahamu, ọ̀rẹ́ rẹ, títí lae?

8 Wọ́n ti ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì ti kọ́ ibi mímọ́ sibẹ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ,

9 nítorí pé tí ibi bá dé bá wa, tabi ìdájọ́, tabi àjàkálẹ̀ àrùn, tabi ìyàn, a óo dúró níwájú ilé yìí ati níwájú rẹ, nítorí orúkọ rẹ wà ninu ilé yìí. A óo ké pè ọ́ ninu ìyọnu wa, o óo gbọ́ tiwa, o óo sì gbà wá.

10 “Nisinsinyii, wo àwọn ọmọ ogun Amoni, ati ti Moabu ati ti Òkè Seiri, àwọn tí o kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli bá jà nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti, o kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n run.

11 Wò ó! Wọ́n ń fi burúkú san ire fún wa, wọ́n ń bọ̀ wá lé wa kúrò lórí ilẹ̀ rẹ, tí o fún wa bí ìní.

12 Ọlọrun wa, dá wọn lẹ́jọ́. Nítorí pé agbára wa kò tó láti dojú kọ ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun wọn tí wọn ń kó bọ̀ wá bá wa jà. A kò mọ ohun tí a lè ṣe, ìwọ ni a gbójú sókè tí à ń wò.”

13 Gbogbo àwọn ọkunrin Juda dúró níwájú OLUWA pẹlu àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn.

14 Ẹ̀mí OLUWA bà lé Jahasieli, ọmọ Sakaraya, ọmọ Bẹnaya, ọmọ Jeieli, ọmọ Matanaya; ọmọ Lefi ni, láti inú ìran Asafu. Ó bá dìde dúró láàrin àwùjọ àwọn eniyan.

15 Ó ní, “Ẹ fetí sí mi, gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati ti Jerusalẹmu ati ọba Jehoṣafati, OLUWA ní kí ẹ má fòyà, kí ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì nítorí ogun ńlá yìí; nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ ó ja ogun ńlá yìí, Ọlọrun ni.

16 Ní ọ̀la, ẹ kógun lọ bá wọn; wọn yóo gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Sisi wá, ẹ óo rí wọn ní òpin àfonífojì ní apá ìlà oòrùn aṣálẹ̀ Jerueli.

17 Ẹ kò ní jagun rárá, ẹ sá dúró ní ààyè yín, kí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo sì rí bí OLUWA yóo ti gba ẹ̀yin ará Juda ati Jerusalẹmu là. Ẹ má fòyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì, Ẹ lọ kò wọ́n lójú lọ́la, OLUWA yóo wà pẹlu yín.”

18 Jehoṣafati dojúbolẹ̀, gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.

19 Ni àwọn ọmọ Lefi láti inú ìdílé Kohati ati ti Kora bá dìde, wọ́n gbóhùn sókè, wọ́n sì yin OLUWA Ọlọrun Israẹli.

20 Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà lọ sí aṣálẹ̀ Tekoa. Bí wọ́n ti ń lọ, Jehoṣafati dúró, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, ẹ gba ohun tí àwọn wolii rẹ̀ wí gbọ́ pẹlu, ẹ óo sì ní ìṣẹ́gun.”

21 Nígbà tí Jehoṣafati bá àwọn eniyan rẹ̀ jíròrò tán, ó yan àwọn tí wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA; tí wọn yóo wọ aṣọ mímọ́, tí wọn yóo sì máa yìn ín bí wọn yóo ti máa lọ níwájú ogun, wọn yóo máa kọrin pé,“Ẹ yin OLUWA!Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ dúró laelae.”

22 Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ìyìn, OLUWA gbẹ̀yìn yọ sí àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu ati ti Òkè Seiri tí wọ́n wá bá àwọn eniyan Juda jà, ó sì tú wọn ká.

23 Àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu gbógun ti àwọn ará Òkè Seiri wọ́n sì pa wọ́n run patapata. Lẹ́yìn náà, wọ́n dojú ìjà kọ ara wọn, wọ́n sì pa ara wọn run.

24 Nígbà tí ogun Juda dé ilé ìṣọ́ tí ó wà ninu aṣálẹ̀, wọ́n wo àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n ti kú sílẹ̀ lọ bẹẹrẹ; kò sí ẹni tí ó sá àsálà ninu wọn.

25 Nígbà tí Jehoṣafati ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti kó ìkógun, wọ́n rí ọpọlọpọ mààlúù, ati ẹrù aṣọ ati nǹkan ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye. Wọ́n kó wọn títí ó fi sú wọn. Odidi ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi kó ìkógun nítorí pé ó ti pọ̀ jù.

26 Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n péjọ ní àfonífojì Beraka. Ibẹ̀ ni wọ́n ti yin OLUWA. Nítorí náà ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí pe ibẹ̀ ní Beraka títí di òní olónìí.

27 Jehoṣafati kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun, nítorí pé OLUWA ti fún un ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

28 Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, wọ́n wọ inú tẹmpili lọ, pẹlu ìró hapu, ati ti dùùrù ati ti fèrè.

29 Ẹ̀rù OLUWA ba ìjọba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí wọ́n gbọ́ pé OLUWA bá àwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Israẹli jagun.

30 Nítorí náà Jehoṣafati jọba ní alaafia, nítorí pé Ọlọrun fún un ní ìsinmi ní gbogbo àyíká rẹ̀.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Jehoṣafati

31 Jehoṣafati jọba lórí Juda, ẹni ọdún marundinlogoji ni nígbà tí ó gorí oyè. Gbogbo ọdún tí ó lò lórí oyè jẹ́ ọdún mẹẹdọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Asuba, ọmọ Ṣilihi.

32 Ó ṣe dáradára gẹ́gẹ́ bí Asa, baba rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA.

33 Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run; àwọn eniyan kò tíì máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọrun àwọn baba ńlá wọn.

34 Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn Jehu ọmọ Hanani, tí ó jẹ́ apá kan ìtàn àwọn ọba Israẹli.

35 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Jehoṣafati, ọba Juda lọ darapọ̀ mọ́ Ahasaya, ọba Israẹli, tí ó jẹ́ eniyan burúkú.

36 Wọ́n jọ kan àwọn ọkọ̀ ojú omi tí yóo lọ sí ìlú Taṣiṣi. Wọ́n kan àwọn ọkọ̀ náà ní Esiongeberi.

37 Elieseri ọmọ Dodafahu, ará Mareṣa fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Jehoṣafati wí. Ó ní, “Nítorí pé o darapọ̀ mọ́ Ahasaya, OLUWA yóo ba ohun tí o ti ṣe tẹ́lẹ̀ jẹ́.” Gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú omi náà rì, wọn kò sì lè lọ sí Taṣiṣi mọ́.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36