Kronika Keji 31 BM

Hesekaya Ṣe Àtúnṣe Ẹ̀sìn

1 Nígbà tí wọ́n parí ayẹyẹ wọnyi, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá síbi àjọ náà lọ sí àwọn ìlú Juda, wọ́n fọ́ gbogbo òpó oriṣa, ati gbogbo igbó oriṣa Aṣera, wọ́n wó gbogbo àwọn pẹpẹ palẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Juda, ti Bẹnjamini, ti Efuraimu ati ti Manase. Nígbà tí wọ́n fọ́ gbogbo wọn túútúú tán, wọ́n pada lọ sí ìlú wọn, olukuluku sì lọ sí orí ilẹ̀ rẹ̀.

2 Hesekaya pín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, olukuluku ní iṣẹ́ tirẹ̀. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà fún ẹbọ sísun, ati ẹbọ alaafia. Àwọn náà ni wọ́n wà fún ati máa ṣe iṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ OLUWA, ati láti máa kọrin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA.

3 Hesekaya a máa fa ẹran kalẹ̀ ninu agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ sísun ti àárọ̀ ati ti àṣáálẹ́, ati fún ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ẹbọ oṣù tuntun ati àwọn ẹbọ mìíràn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.

4 Ọba pàṣẹ fún àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé kí wọ́n mú ọrẹ tí ó tọ́ sí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wa, kí wọ́n lè fi gbogbo àkókò wọn sílẹ̀ láti máa kọ́ àwọn eniyan ní òfin OLUWA.

5 Ní kété tí àṣẹ yìí tàn káàkiri, wọ́n mú ọpọlọpọ àkọ́so ọkà, ati ọtí ati òróró ati oyin, ati àwọn nǹkan irè oko mìíràn wá. Wọ́n tún san ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí wọ́n ní.

6 Àwọn ọmọ Israẹli ati ti Juda tí wọn ń gbé àwọn ìlú Juda náà san ìdámẹ́wàá mààlúù ati aguntan, ati ti àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n kó wọn jọ bí òkítì.

7 Ní oṣù kẹta ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ìdámẹ́wàá náà jọ, wọ́n kó wọn jọ tán ní oṣù keje.

8 Nígbà tí Hesekaya ati àwọn ìjòyè wá wo àwọn ìdámẹ́wàá tí wọ́n kójọ bí òkítì, wọ́n yin OLUWA, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

9 Hesekaya bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi nípa àwọn òkítì náà.

10 Asaraya, olórí alufaa, láti ìdílé Sadoku dá a lóhùn pé: “Láti ìgbà tí àwọn eniyan ti bẹ̀rẹ̀ sí mú ẹ̀bùn wá sí ilé OLUWA ni a ti ń jẹ àjẹyó, tí ó sì ń ṣẹ́kù, nítorí pé OLUWA ti bukun àwọn eniyan rẹ̀, ni a fi ní àjẹṣẹ́kù tí ó pọ̀ tó yìí.”

11 Hesekaya bá pàṣẹ pé kí wọ́n tọ́jú àwọn yàrá tó wà ninu ilé OLUWA, wọ́n bá ṣe ìtọ́jú wọn.

12 Wọ́n ṣolóòótọ́ ní kíkó àwọn ẹ̀bùn, ati ìdámẹ́wàá àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ náà pamọ́. Konanaya, ọmọ Lefi, ni olórí àwọn tí wọn ń bojútó wọn, Ṣimei, arakunrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀.

13 Jehieli, Asasaya, ati Nahati; Asaheli, Jerimotu, ati Josabadi; Elieli, Isimakaya, ati Mahati ati Bẹnaya ni àwọn alabojuto tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ Konanaya ati Ṣimei, arakunrin rẹ̀. Hesekaya ọba ati Asaraya olórí ilé OLUWA ni wọ́n yàn wọ́n sí iṣẹ́ náà.

14 Kore, ọmọ Imina, ọmọ Lefi kan tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn tẹmpili ni ó ń ṣe alákòóso ọrẹ àtinúwá tí wọ́n mú wá fún Ọlọrun. Òun ni ó sì ń pín àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA ati àwọn ọrẹ mímọ́ jùlọ.

15 Edẹni, Miniamini, ati Jeṣua, Ṣemaaya, Amaraya, ati Ṣekanaya, ń ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ìlú àwọn alufaa, wọ́n ń pín àwọn ẹ̀bùn náà láì ṣe ojuṣaaju àwọn arakunrin wọn, lọ́mọdé ati lágbà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí;

16 àfi àwọn ọkunrin, láti ẹni ọdún mẹta sókè, tí wọ́n ti kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé ìdílé, gbogbo awọn tí wọ́n wọ ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olukuluku ṣe gbà lójoojúmọ́, fun iṣẹ́ ìsìn wọn gẹ́gẹ́ bí ipò wọn, nípa ìpín wọn.

17 Wọ́n kọ orúkọ àwọn alufaa ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún sókè ni wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ipò wọn ati ìpín wọn.

18 Àwọn alufaa kọ orúkọ wọn sílẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, àwọn aya wọn, àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin gbogbo wọn patapata, nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nípa pípa ara wọn mọ́.

19 Ninu àwọn alufaa tí wọ́n wà ní ìlú àwọn ìran Aaroni ní ilẹ̀ gbogbogbòò ati ninu ìletò wọn, ni àwọn olóòótọ́ wà, tí wọ́n yàn láti máa pín oúnjẹ fún olukuluku ninu àwọn alufaa ati àwọn tí orúkọ wọn wà ninu àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn Lefi.

20 Jákèjádò Juda ni Hesekaya ti ṣe ètò yìí, ó ṣe ohun tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ òtítọ́ lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀.

21 Gbogbo ohun tí ó ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òfin ati àṣẹ Ọlọ́run, ati wíwá tí ó wá ojurere Ọlọrun, gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe tọkàntọkàn, ó sì dára fún un.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36