Kronika Keji 24 BM

Joaṣi, Ọba Juda

1 Ọmọ ọdún meje ni Joaṣi nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ogoji ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibaya, ará Beeriṣeba.

2 Joaṣi ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé Jehoiada alufaa.

3 Jehoiada fẹ́ iyawo meji fún un, wọ́n sì bímọ fún un lọkunrin ati lobinrin.

4 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Joaṣi pinnu láti tún ilé OLUWA ṣe.

5 Ó pe gbogbo àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ máa gba owó lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti máa fi tún ilé OLUWA Ọlọrun yín ṣe ní ọdọọdún. Ẹ mójútó iṣẹ́ náà kí ẹ sì ṣe é kíákíá.” Ṣugbọn àwọn alufaa kò tètè lọ.

6 Nítorí náà, ọba ranṣẹ pe Jehoiada tí ó jẹ́ olórí wọn, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Lefi lọ máa gba owó fún àgọ́ ẹ̀rí lọ́wọ́ àwọn eniyan Juda ati Jerusalẹmu bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pa á láṣẹ?”

7 (Nítorí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Atalaya, obinrin burúkú n nì, ti fọ́ ilé Ọlọrun, wọ́n sì ti kó gbogbo ohun èlò mímọ́ ibẹ̀, wọ́n ti lò ó fún oriṣa Baali.)

8 Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe àpótí kan tí àwọn eniyan yóo máa sọ owó sí, kí wọ́n sì gbé e sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA.

9 Wọ́n kéde káàkiri Jerusalẹmu ati Juda pé kí wọ́n máa mú owó orí wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ Ọlọrun ti pàṣẹ fún Israẹli ninu aṣálẹ̀.

10 Gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo eniyan fi tayọ̀tayọ̀ mú owó orí wọn wá, wọ́n ń sọ ọ́ sinu àpótí náà títí tí ó fi kún.

11 Nígbà tí àwọn Lefi bá gbé àpótí náà wá fún àwọn òṣìṣẹ́ ọba, tí wọ́n sì rí i pé owó pọ̀ ninu rẹ̀, akọ̀wé ọba ati aṣojú olórí alufaa yóo da owó kúrò ninu àpótí, wọn yóo sì gbé e pada sí ààyè rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ní ojoojumọ, wọ́n sì rí ọpọlọpọ owó kó jọ.

12 Ọba ati Jehoiada gbé owó náà fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso iṣẹ́ ilé OLUWA, wọ́n gba àwọn ọ̀mọ̀lé, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn alágbẹ̀dẹ irin ati ti bàbà, láti tún ilé OLUWA ṣe.

13 Gbogbo àwọn tí wọ́n kópa ninu iṣẹ́ náà fi tagbára tagbára ṣe é. Iṣẹ́ náà tẹ̀síwájú títí tí wọ́n fi tún ilé OLUWA náà ṣe tán, tí ó sì rí bíi ti iṣaaju tí ó sì tún lágbára sí i.

14 Nígbà tí wọ́n tún ilé OLUWA náà ṣe tán, wọ́n kó owó tí ó kù pada sọ́dọ̀ ọba ati Jehoiada. Wọ́n fi owó náà ṣe àwọn ohun èlò fún ìsìn ati ẹbọ sísun ní ilé OLUWA, ati àwo fún turari ati ohun èlò wúrà ati fadaka.Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé OLUWA lojoojumọ, ní gbogbo àkókò Jehoiada.

Wọ́n Yí Ètò ìjọba Jehoiada pada

15 Nígbà tí Jehoiada dàgbà tí ó di arúgbó, ó kú nígbà tí ó pé ẹni aadoje (130) ọdún.

16 Wọ́n sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi nítorí iṣẹ́ rere tí ó ṣe ní Israẹli fún Ọlọrun ati ní ilé mímọ́ rẹ̀.

17 Ṣugbọn nígbà tí Jehoiada kú, àwọn ìjòyè ní Juda wá kí ọba, wọ́n sì júbà rẹ̀, ó sì gba ìmọ̀ràn wọn.

18 Wọ́n kọ ilé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì ń sin oriṣa Aṣera ati àwọn ère mìíràn. Nítorí ìwà burúkú yìí, inú bí OLUWA sí Juda ati Jerusalẹmu.

19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA rán àwọn wolii sí wọn láti darí wọn pada sọ́dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ fún wọn, wọ́n kọ etí dídi sí àwọn wolii.

20 Nígbà tí ó yá, Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Sakaraya, ọmọ Jehoiada alufaa, ó bá dìde dúró láàrin àwọn eniyan, ó ní, “Ọlọrun ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi tàpá sí òfin òun OLUWA; ṣé ẹ kò fẹ́ kí ó dára fun yín ni? Nítorí pé, ẹ ti kọ OLUWA sílẹ̀, òun náà sì ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ”

21 Ṣugbọn wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, ọba pàṣẹ pé kí wọn sọ ọ́ lókùúta pa ninu gbọ̀ngàn ilé OLUWA.

22 Joaṣi ọba kò ranti oore tí Jehoiada, baba Sakaraya ṣe fún un, ṣugbọn ó pa ọmọ rẹ̀. Nígbà tí ó sì ń kú lọ, ó ní, “Kí OLUWA wo ohun tí o ṣe yìí, kí ó sì gbẹ̀san.”

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Joaṣi

23 Bí ọdún náà ti ń dópin lọ, àwọn ọmọ ogun Siria gbógun ti Joaṣi. Nígbà tí wọ́n dé Juda ati Jerusalẹmu, wọ́n pa gbogbo àwọn ìjòyè wọn, wọ́n sì kó gbogbo ìkógun wọn ranṣẹ sí Damasku.

24 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n wá, sibẹsibẹ OLUWA fi ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ ogun Juda lé wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA Ọlọrun baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìdájọ́ Joaṣi ọba.

25 Ọba fara gbọgbẹ́ ninu ogun náà, nígbà tí àwọn ogun Siria sì lọ tán, àwọn balogun rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn nítorí pé ó pa ọmọ Jehoiada alufaa, wọ́n sì pa á lórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, ṣugbọn kì í ṣe inú ibojì àwọn ọba.

26 Àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba ni Sabadi, ọmọ Ṣimeati ará Amoni, ati Jehosabadi ọmọ Ṣimiriti ará Moabu.

27 Ìtàn àwọn ọmọ rẹ̀, ati ọpọlọpọ àsọtẹ́lẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀, ati bí ó ti tún ilé Ọlọrun ṣe wà, tí a kọ ọ́ sinu ìwé Ìtàn Àwọn Ọba. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36