13 Ọba kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà, ó gbójú mọ́ wọn,
14 ó sọ̀rọ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́ fún un, ó ní, “Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn èmi óo tún fi kún àjàgà náà. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi máa ta yín.”
15 Ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé ọwọ́ Ọlọrun ni àyípadà yìí ti wá, kí ó lè mú ohun tí ó ní kí wolii Ahija, ará Ṣilo, sọ fún Jeroboamu, ọmọ Nebati, ṣẹ.
16 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Rehoboamu kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dáhùn pé,“Kí ló kàn wá pẹlu ilé Dafidi?Kí ló pa wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese?Ẹ pada sinu àgọ́ yín, ẹ̀yin ọmọ IsraẹliDafidi, fọwọ́ mú ilé rẹ.”Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lọ sí ilé wọn,
17 ṣugbọn Rehoboamu jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda.
18 Ọba rán Hadoramu tí ó jẹ́ olórí àwọn akóniṣiṣẹ́ sí àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa. Rehoboamu ọba bá yára bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá àsálà lọ sí Jerusalẹmu.
19 Láti ìgbà náà lọ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ń bá ilé Dafidi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí.