8 Ṣugbọn Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà. Ó lọ jíròrò pẹlu àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọn ń bá a ṣiṣẹ́, ó bi wọ́n pé,
9 “Kí ni èsì tí ó yẹ kí n fún àwọn tí wọ́n sọ fún mi pé kí n sọ àjàgà tí baba mi gbé bọ àwọn lọ́rùn di fúfúyẹ́?”
10 Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé, “Lọ sọ fún wọn pé, ‘Ìka ọwọ́ mi tí ó kéré jù yóo tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ.
11 Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn tèmi yóo tún wúwo ju ti baba mi lọ. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi ta yín.’ ”
12 Ní ọjọ́ kẹta, Jeroboamu pẹlu àwọn ọmọ Israẹli bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí àdéhùn wọn.
13 Ọba kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà, ó gbójú mọ́ wọn,
14 ó sọ̀rọ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́ fún un, ó ní, “Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn èmi óo tún fi kún àjàgà náà. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi máa ta yín.”