1 Láìpẹ́, lẹ́yìn tí Rehoboamu fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ tí ó di alágbára, òun ati àwọn eniyan rẹ̀ kọ òfin OLUWA sílẹ̀.
2 Nígbà tí ó di ọdún karun-un ìjọba rẹ̀, Ọlọrun fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí aiṣootọ rẹ̀. Ṣiṣaki ọba Ijipti gbógun ti Jerusalẹmu pẹlu ẹgbẹfa (1,200) kẹ̀kẹ́ ogun,
3 ati ọ̀kẹ́ mẹta (60,000) ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e láti Ijipti. Àwọn ará Libia, àwọn ará Sukiimu, ati àwọn ará Etiopia wà ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
4 Ó gba gbogbo ìlú olódi Juda títí ó fi dé Jerusalẹmu.
5 Lẹ́yìn náà, wolii Ṣemaaya lọ bá Rehoboamu ati gbogbo àwọn olóyè Juda, tí wọ́n ti péjọ sí Jerusalẹmu lórí ọ̀rọ̀ Ṣiṣaki ọba Ijipti. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA ní ẹ ti kọ òun sílẹ̀, nítorí náà ni òun ṣe fi yín lé Ṣiṣaki lọ́wọ́.”
6 Àwọn ìjòyè ní Israẹli ati Rehoboamu ọba bá wí pẹlu ìtẹríba pé, “Olódodo ni Ọlọrun.”
7 Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti ronupiwada, ó sọ fún wolii Ṣemaaya pé, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, òun kò ní pa wọ́n run mọ́, ṣugbọn òun óo gbà wọ́n sílẹ̀ díẹ̀. Òun kò ní fi agbára lo Ṣiṣaki láti rọ̀jò ibinu òun sórí Jerusalẹmu.