13 Rehoboamu fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní Jerusalẹmu, agbára rẹ̀ sì pọ̀ sí i. Ọmọ ọdún mọkanlelogoji ni nígbà tí ó jọba. Ó jọba fún ọdún mẹtadinlogun ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin àwọn ẹ̀yà yòókù, pé kí wọ́n ti máa sin òun. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Naama, ará Amoni.
14 Rehoboamu ṣe nǹkan burúkú, nítorí pé kò fi ọkàn sí ati máa rìn ní ìlànà OLUWA.
15 Gbogbo ohun tí Rehoboamu ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn wolii Ṣemaaya, ati sinu ìwé Ido aríran. Nígbà gbogbo ni ogun máa ń wà láàrin Rehoboamu ati Jeroboamu.
16 Nígbà tí Rehoboamu kú, wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, níbi ibojì àwọn baba rẹ̀. Abija ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.