9 Ẹ ti lé àwọn alufaa OLUWA kúrò lọ́dọ̀ yín: àwọn ọmọ Aaroni, ati àwọn ọmọ Lefi. Ẹ yan alufaa mìíràn dípò wọn bí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ti ṣe. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá ti mú akọ mààlúù tabi aguntan meje wá, ẹ̀ ń yà á sí mímọ́ fún iṣẹ́ alufaa àwọn oriṣa tí kì í ṣe Ọlọrun.
10 “Ṣugbọn ní tiwa, OLUWA Ọlọrun ni à ń sìn; a kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ọmọ Aaroni ni àwọn alufaa wa, àwọn ọmọ Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́.
11 Ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́ ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun, tí wọ́n sì ń sun turari. Wọ́n ń fi àkàrà ìfihàn sórí tabili wúrà. Ní alaalẹ́, wọ́n ń tan fìtílà wúrà lórí ọ̀pá fìtílà rẹ̀; nítorí àwa ń ṣe ohun tí Ọlọrun wa pa láṣẹ fún wa, ṣugbọn ẹ̀yin ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
12 Ọlọrun wà pẹlu wa, òun fúnrarẹ̀ ni aṣaaju wa. Àwọn alufaa rẹ̀ wà níhìn-ín láti fun fèrè láti pè wá kí á gbógun tì yín. Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ má ṣe bá OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín jà, nítorí ẹ kò ní borí.”
13 Ṣugbọn Jeroboamu ti rán ọ̀wọ́ ọmọ ogun kan lọ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Juda látẹ̀yìn. Àwọn ọmọ ogun Jeroboamu wà níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, àwọn tí ó rán tí wọ́n sápamọ́ sì wà lẹ́yìn wọn.
14 Nígbà tí Juda rí i pé ogun wà níwájú ati lẹ́yìn wọn, wọ́n ké pe OLUWA, àwọn alufaa sì fọn fèrè ogun.
15 Àwọn ọmọ ogun Juda hó ìhó ogun, bí wọ́n sì ti kígbe ni Ọlọrun ṣẹgun Jeroboamu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli fún Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda.