1 Nígbà tí Abija ọba kú, wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní àkókò rẹ̀, alaafia wà ní ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́wàá.
2 Asa ṣe ohun tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì dùn mọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ó mú inú Ọlọrun dùn.
3 Ó kó àwọn pẹpẹ àjèjì ati àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn kúrò, ó wó àwọn òpó oriṣa wọn lulẹ̀, ó sì fọ́ ère Aṣera.
4 Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Juda láti wá ojurere OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn ati láti pa òfin rẹ̀ mọ́.