1 Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Asaraya ọmọ Odedi.
2 Ó lọ pàdé Asa, ó wí fún un pé, “Gbọ́ mi, ìwọ Asa, ati gbogbo ẹ̀yin ọmọ Juda ati ti Bẹnjamini, OLUWA wà pẹlu yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin náà bá wà pẹlu rẹ̀. Bí ẹ bá wá a, ẹ óo rí i. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun náà yóo kọ̀ yín sílẹ̀.
3 Ọjọ́ pẹ́, tí Israẹli ti wà láìní Ọlọrun òtítọ́, wọn kò ní alufaa tí ń kọ́ ni, wọn kò sì ní òfin.
4 Ṣugbọn nígbà tí ìyọnu dé, wọ́n yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Wọ́n wá OLUWA, wọ́n sì rí i.
5 Ní àkókò náà, kò sí ìbàlẹ̀ ọkàn fún àwọn tí wọn ń jáde ati àwọn tí wọ́n ń wọlé, nítorí ìdààmú ńlá dé bá àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà.
6 Orílẹ̀-èdè kan ń pa ekeji run, ìlú kan sì ń pa ekeji rẹ́, nítorí Ọlọrun mú oniruuru ìpọ́njú bá wọn.