1 Jehoṣafati ọba Juda pada ní alaafia sí ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
2 Ṣugbọn Jehu, aríran, ọmọ Hanani lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ṣé ó dára kí o máa ran eniyan burúkú lọ́wọ́, kí o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra OLUWA? Nítorí èyí, ibinu OLUWA ru sí ọ.
3 Sibẹsibẹ àwọn nǹkankan wà tí o ṣe tí ó dára, o run àwọn ère oriṣa Aṣera ní ilẹ̀ yìí, o sì ti ṣe ọkàn rẹ gírí láti tẹ̀lé Ọlọ́run.”
4 Jerusalẹmu ni Jehoṣafati ń gbé, ṣugbọn a máa lọ jákèjádò ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli, láti Beeriṣeba títí dé agbègbè olókè Efuraimu, a máa káàkiri láti yí wọn lọ́kàn pada sí OLUWA Ọlọrun baba wọn.