Kronika Keji 19:4-10 BM

4 Jerusalẹmu ni Jehoṣafati ń gbé, ṣugbọn a máa lọ jákèjádò ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli, láti Beeriṣeba títí dé agbègbè olókè Efuraimu, a máa káàkiri láti yí wọn lọ́kàn pada sí OLUWA Ọlọrun baba wọn.

5 Ó yan àwọn adájọ́ ní gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda.

6 Ó kìlọ̀ fún wọn ó ní, “Ẹ ṣọ́ra gan-an, nítorí pé kì í ṣe eniyan ni ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún, OLUWA ni. Ẹ sì ranti pé OLUWA wà lọ́dọ̀ yín bí ẹ ti ń ṣe ìdájọ́.

7 Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì ṣọ́ra pẹlu àwọn nǹkan tí ẹ ó máa ṣe, nítorí pé OLUWA Ọlọrun wa kì í yí ìdájọ́ po, kì í ṣe ojuṣaaju, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”

8 Jehoṣafati tún yan àwọn kan ní Jerusalẹmu ninu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn alufaa ati àwọn baálé baálé ní Israẹli, láti máa fi òfin OLUWA ṣe ìdájọ́ ati láti máa yanjú ẹjọ́ tí kò bá di àríyànjiyàn.

9 Ó kìlọ̀ fún wọn, ó ní “Ohun tí ẹ gbọdọ̀ máa fi tọkàntọkàn ṣe, pẹlu ìbẹ̀rù OLUWA ati òtítọ́ nìyí:

10 Nígbàkúùgbà tí àwọn arakunrin yín bá mú ẹjọ́ wá siwaju yín láti ìlú kan, kì báà ṣe ti ìtàjẹ̀sílẹ̀, tabi ti nǹkan tí ó jẹ mọ́ òfin, tabi àṣẹ, tabi ìlànà, ẹ níláti ṣe àlàyé fún wọn kí wọ́n má baà jẹ̀bi níwájú OLUWA, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí ẹ̀yin náà ati àwọn arakunrin yín. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ máa ṣe kí ẹ má baà jẹ̀bi.