5 Àwọn tí wọ́n rí oúnjẹ jẹ lájẹyó ríti di ẹni tí ń fi ara wọn ṣọfà nítorí oúnjẹ,ṣugbọn àwọn tí ebi ti ń pa tẹ́lẹ̀ rí tí ń jẹ àjẹyó.Àgàn ti di ọlọ́mọ meje,ọlọ́mọ pupọ ti di aláìní.
6 OLUWA ni ó lè pa eniyan tán,kí ó sì tún jí i dìde;òun ni ó lè múni lọ sinu isà òkú,tí ó sì tún lè fani yọ kúrò níbẹ̀.
7 OLUWA ni ó lè sọni di aláìní,òun náà ni ó sì lè sọ eniyan di ọlọ́rọ̀.Òun ni ó ń gbéni ga,òun náà ni ó sì ń rẹ eniyan sílẹ̀.
8 OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀;ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀,láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba,kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá.Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé,òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn.
9 “Yóo pa àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ mọ́,ṣugbọn yóo mú kí àwọn eniyan burúkú parẹ́ ninu òkùnkùn;nítorí pé, kì í ṣe nípa agbára eniyan, ni ẹnikẹ́ni lè fi ṣẹgun.
10 Àwọn ọ̀tá OLUWA yóo parun;OLUWA yóo sán ààrá pa wọ́n láti ojú ọ̀run wá.OLUWA yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé,yóo fún ọba rẹ̀ lágbára,yóo sì fún ẹni tí ó yàn ní ìṣẹ́gun.”
11 Lẹ́yìn náà, Elikana pada sí ilé rẹ̀ ní Rama. Ṣugbọn Samuẹli dúró sí Ṣilo, ó ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, lábẹ́ alufaa Eli.