14 Ọlọrun si wipe, Ki awọn imọlẹ ki o wà li ofurufu ọrun, lati pàla ọsán on oru; ki nwọn ki o si ma wà fun àmi, ati fun akoko, ati fun ọjọ́, ati fun ọdún:
15 Ki nwọn ki o si jẹ́ imọlẹ li ofurufu ọrun, lati mọlẹ sori ilẹ: o si ri bẹ̃.
16 Ọlọrun si dá imọlẹ nla meji; imọlẹ ti o tobi lati ṣe akoso ọsán, ati imọlẹ ti o kere lati ṣe akoso oru: o si dá awọn irawọ pẹlu.
17 Ọlọrun si sọ wọn lọjọ̀ li ofurufu ọrun, lati ma tàn imọlẹ sori ilẹ,
18 Ati lati ṣe akoso ọsán ati akoso oru, ati lati pàla imọlẹ on òkunkun: Ọlọrun si ri pe o dara.
19 Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹrin.
20 Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun.