16 Ọlọrun si dá imọlẹ nla meji; imọlẹ ti o tobi lati ṣe akoso ọsán, ati imọlẹ ti o kere lati ṣe akoso oru: o si dá awọn irawọ pẹlu.
17 Ọlọrun si sọ wọn lọjọ̀ li ofurufu ọrun, lati ma tàn imọlẹ sori ilẹ,
18 Ati lati ṣe akoso ọsán ati akoso oru, ati lati pàla imọlẹ on òkunkun: Ọlọrun si ri pe o dara.
19 Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹrin.
20 Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun.
21 Ọlọrun si dá erinmi nlanla ati ẹdá alãye gbogbo ti nrakò, ti omi kún fun li ọ̀pọlọpọ ni irú wọn, ati ẹiyẹ abiyẹ ni irú rẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara.
22 Ọlọrun si súre fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ẹ si mã rẹ̀, ki ẹ kún inu omi li okun, ki ẹiyẹ ki o si ma rẹ̀ ni ilẹ.