1 IRAN awọn ọmọ Noa ni wọnyi, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti: ati fun wọn li a si bí ọmọ lẹhin kíkun-omi.
2 Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi.
3 Ati awọn ọmọ Gomeri, Aṣkenasi, ati Rifati, ati Togarma.
4 Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu.
5 Lati ọdọ awọn wọnyi li a ti pín erekuṣu awọn orilẹ-ède ni ilẹ wọn, olukuluku gẹgẹ bi ohùn rẹ̀; gẹgẹ bi idile wọn, li orilẹ-ède wọn.
6 Ati awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, ati Futi, ati Kenaani.
7 Ati awọn ọmọ Kuṣi; Seba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka; ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba, ati Dedani.