27 Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla,
28 Ati Obali, ati Abimaeli, ati Ṣeba,
29 Ati Ofiri, ati Hafila, ati Jobabu: gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Joktani.
30 Ibugbe wọn si ti Meṣa lọ, bi iwọ ti nlọ si Sefari, oke kan ni ìla-õrùn.
31 Awọn wọnyi li ọmọ Ṣemu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, li orilẹ-ède wọn.
32 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Noa, gẹgẹ bi iran wọn, li orilẹ-ède wọn: lati ọwọ́ awọn wọnyi wá li a ti pín orilẹ-ède aiye lẹhin kíkun-omi.