4 Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu.
5 Lati ọdọ awọn wọnyi li a ti pín erekuṣu awọn orilẹ-ède ni ilẹ wọn, olukuluku gẹgẹ bi ohùn rẹ̀; gẹgẹ bi idile wọn, li orilẹ-ède wọn.
6 Ati awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, ati Futi, ati Kenaani.
7 Ati awọn ọmọ Kuṣi; Seba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka; ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba, ati Dedani.
8 Kuṣi si bí Nimrodu: on si bẹ̀rẹ si idi alagbara li aiye.
9 On si ṣe ogbóju ọdẹ niwaju OLUWA: nitori na li a ṣe nwipe, Gẹgẹ bi Nimrodu ogbóju ọdẹ niwaju OLUWA.
10 Ipilẹṣẹ ijọba rẹ̀ ni Babeli, ati Ereki, ati Akkadi, ati Kalne, ni ilẹ Ṣinari.