11 Ẹnyin o si kọ ara nyin ni ilà; on ni yio si ṣe àmi majẹmu lãrin temi ti nyin.
12 Ẹniti o ba si di ọmọkunrin ijọ mẹjọ ninu nyin li a o kọ ni ilà, gbogbo ọmọkunrin ni iran-iran nyin, ati ẹniti a bí ni ile, tabi ti a fi owo rà lọwọ alejo, ti ki iṣe irú-ọmọ rẹ.
13 Ẹniti a bí ni ile rẹ, ati ẹniti a fi owo rẹ rà, a kò le ṣe alaikọ ọ ni ilà: bẹ̃ni majẹmu mi yio si wà li ara nyin ni majẹmu aiyeraiye.
14 Ati ọmọkunrin alaikọlà ti a kò kọ ni ilà ara rẹ̀, ọkàn na li a o si ké kuro ninu awọn enia rẹ̀, o dà majẹmu mi.
15 Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Bi o ṣe ti Sarai, aya rẹ nì, iwọ ki yio pè orukọ rẹ̀ ni Sarai mọ́, bikoṣe Sara li orukọ rẹ̀ yio ma jẹ.
16 Emi o si busi i fun u, emi o si bùn ọ li ọmọkunrin kan pẹlu lati ọdọ rẹ̀ wá, bẹ̃li emi o si busi i fun u, on o si ṣe iya ọ̀pọ orilẹ-ède; awọn ọba enia ni yio ti ọdọ rẹ̀ wá.
17 Nigbana li Abrahamu dojubolẹ, o si rẹrin, o si wi li ọkàn rẹ̀ pe, A o ha bímọ fun ẹni ọgọrun ọdún? Sara ti iṣe ẹni ãdọrun ọdún yio ha bímọ bi?