3 Abramu si dojubolẹ; Ọlọrun si ba a sọ̀rọ pe,
4 Bi o ṣe ti emi ni, kiyesi i, majẹmu mi wà pẹlu rẹ, iwọ o si ṣe baba orilẹ-ède pupọ̀.
5 Bẹ̃li a ki yio si pe orukọ rẹ ni Abramu mọ́, bikoṣe Abrahamu li orukọ rẹ yio jẹ; nitoriti mo ti sọ ọ di baba orilẹ-ède pupọ̀.
6 Emi o si mu ọ bí si i pupọpupọ, ọ̀pọ orilẹ-ède li emi o si mu ti ọdọ rẹ wá, ati awọn ọba ni yio ti inu rẹ jade wá.
7 Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ lãrin temi tirẹ, ati lãrin irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn, ni majẹmu aiyeraiye, lati ma ṣe Ọlọrun rẹ, ati ti irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ.
8 Emi o si fi ilẹ ti iwọ ṣe alejo nibẹ̀ fun ọ, ati fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ, gbogbo ilẹ Kenaani ni iní titi lailai; emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn.
9 Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Nitorina ki iwọ ki o ma pa majẹmu mi mọ́, iwọ, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn.