30 Loti si jade kuro ni Soari: o si ngbé ori oke, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nitoriti o bẹ̀ru ati gbé Soari: o si ngbé inu ihò, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji.
31 Eyi akọbi si wi fun atẹle pe, Baba wa gbó, kò si sí ọkunrin kan li aiye mọ́ ti yio wọle tọ̀ wa wá gẹgẹ bi iṣe gbogbo aiye.
32 Wá, jẹ ki a mu baba wa mu ọti-waini, awa o si sùn tì i, ki a le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa.
33 Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na: eyi akọbi wọle tọ̀ ọ, o si sùn tì baba rẹ̀; on kò si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide.
34 O si ṣe, ni ijọ́ keji, ni ẹgbọn wi fun aburo pe, kiyesi i, emi sùn tì baba mi li oru aná: jẹ ki a si mu u mu ọti-waini li oru yi pẹlu: ki iwọ ki o si wọle, ki o si sùn tì i, ki awa ki o le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa.
35 Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na pẹlu: aburo si dide, o si sùn tì i, on kò si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide.
36 Bẹ̃li awọn ọmọbinrin Loti mejeji loyun fun baba wọn.