12 Abrahamu si tẹriba niwaju awọn enia ilẹ na.
13 O si wi fun Efroni, li eti awọn enia ilẹ na pe, Njẹ bi iwọ o ba fi i fun mi, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ti emi: emi o san owo oko na fun ọ; gbà a lọwọ mi, emi o si sin okú mi nibẹ̀.
14 Efroni si da Abrahamu li ohùn, o wi fun u pe,
15 Oluwa mi, gbọ́ ti emi: irinwo òṣuwọn ṣekeli fadaka ni ilẹ jẹ; kili eyini lãrin temi tirẹ? sa sin okú rẹ.
16 Abrahamu si gbọ́ ti Efroni; Abrahamu si wọ̀n iye fadaka na fun Efroni, ti o sọ li eti awọn ọmọ Heti, irinwo òṣuwọn ṣekeli fadaka, ti o kọja lọdọ awọn oniṣòwo.
17 Oko Efroni ti o wà ni Makpela, ti o wà niwaju Mamre, oko na, ati ihò ti o wà ninu rẹ̀, ati gbogbo igi ti o wà ni oko na, ti o wà ni gbogbo ẹba rẹ̀ yika, li a ṣe daju,
18 Fun Abrahamu ni ilẹ-ini, li oju awọn ọmọ Heti, li oju gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀.