48 Emi si tẹriba, mo si wolẹ fun OLUWA, mo si fi ibukún fun OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, ti o mu mi tọ̀ ọ̀na titọ lati mu ọmọbinrin arakunrin oluwa mi fun ọmọ rẹ̀ wá.
49 Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin o ba bá oluwa mi lò inu rere ati otitọ, ẹ wi fun mi: bi bẹ̃ si kọ; ẹ wi fun mi: ki emi ki o le pọ̀ si apa ọtún, tabi si òsi.
50 Nigbana ni Labani ati Betueli dahùn nwọn si wipe, Lọdọ OLUWA li ohun na ti jade wá: awa kò le sọ rere tabi buburu fun ọ.
51 Wò o, Rebeka niyi niwaju rẹ, mu u, ki o si ma lọ, ki on ki o si ma ṣe aya ọmọ oluwa rẹ, bi OLUWA ti wi.
52 O si ṣe, nigbati iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ọ̀rọ wọn, o wolẹ fun OLUWA.
53 Iranṣẹ na si yọ ohun èlo fadaka, ati èlo wurà jade, ati aṣọ, o si fi wọn fun Rebeka: o si fi ohun iyebiye pẹlu fun arakunrin rẹ̀ ati fun iya rẹ̀.
54 Nwọn si jẹ, nwọn si mu, on ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn si wọ̀ nibẹ̀ li oru ijọ́ na; nwọn si dide li owurọ̀, o si wipe, Ẹ rán mi lọ si ọdọ oluwa mi.