60 Nwọn si súre fun Rebeka, nwọn si wi fun u pe, Iwọ li arabinrin wa, ki iwọ, ki o si ṣe iya ẹgbẹgbẹrun lọnà ẹgbãrun, ki irú-ọmọ rẹ ki o si ni ẹnubode awọn ti o korira wọn.
61 Rebeka si dide, ati awọn omidan rẹ̀, nwọn si gùn awọn ibakasiẹ, nwọn si tẹle ọkunrin na: iranṣẹ na si mu Rebeka, o si ba tirẹ̀ lọ.
62 Isaaki si nti ọ̀na kanga Lahai-roi mbọ̀wá; nitori ilu ìha gusù li on ngbé.
63 Isaaki si jade lọ ṣe àṣaro li oko li aṣalẹ: o si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri i, si kiyesi i, awọn ibakasiẹ mbọ̀wá.
64 Rebeka si gbé oju rẹ̀ soke, nigbati o ri Isaaki, o sọkalẹ lori ibakasiẹ.
65 Nitori ti o ti bi iranṣẹ na pe, ọkunrin ewo li o nrìn bọ̀ li oko lati wá pade wa nì? Iranṣẹ na si ti wi fun u pe, oluwa mi ni: nitori na li o ṣe mu iboju o fi bò ara rẹ̀.
66 Iranṣẹ na si rò ohun gbogbo ti on ṣe fun Isaaki.