63 Isaaki si jade lọ ṣe àṣaro li oko li aṣalẹ: o si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri i, si kiyesi i, awọn ibakasiẹ mbọ̀wá.
64 Rebeka si gbé oju rẹ̀ soke, nigbati o ri Isaaki, o sọkalẹ lori ibakasiẹ.
65 Nitori ti o ti bi iranṣẹ na pe, ọkunrin ewo li o nrìn bọ̀ li oko lati wá pade wa nì? Iranṣẹ na si ti wi fun u pe, oluwa mi ni: nitori na li o ṣe mu iboju o fi bò ara rẹ̀.
66 Iranṣẹ na si rò ohun gbogbo ti on ṣe fun Isaaki.
67 Isaaki si mu u wá si inu agọ́ Sara, iya rẹ̀, o si mu Rebeka, o di aya rẹ̀; o si fẹ́ ẹ; a si tu Isaaki ninu lẹhin ikú iya rẹ̀.