36 O si wipe, A kò ha pè orukọ rẹ̀ ni Jakobu ndan? nitori o jì mi li ẹsẹ̀ ni ìgba meji yi: o gbà ogún-ibi lọwọ mi; si kiyesi i, nisisiyi o si gbà ire mi lọ. O si wipe, Iwọ kò ha pa ire kan mọ́ fun mi?
37 Isaaki si dahùn o si wi fun Esau pe, Wõ, emi ti fi on ṣe oluwa rẹ, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li emi ti fi ṣe iranṣẹ rẹ̀; ati ọkà ati ọti-waini ni mo fi gbè e: ewo li emi o ha ṣe fun ọ nisisiyi, ọmọ mi?
38 Esau si wi fun baba rẹ̀ pe, Ire kanṣoṣo li o ni iwọ baba mi? sure fun mi, ani fun mi pẹlu, baba mi? Esau si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun.
39 Isaaki baba rẹ̀ si dahùn o si wi fun u pe, Wõ, ibujoko rẹ yio jẹ ọrá ilẹ, ati ibi ìri ọrun lati oke wá;
40 Nipa idà rẹ ni iwọ o ma gbé, iwọ o si ma sìn arakunrin rẹ; yio si ṣe nigbati iwọ ba di alagbara tan, iwọ o já àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ.
41 Esau si korira Jakobu nitori ire ti baba rẹ̀ su fun u: Esau si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọjọ́ ọ̀fọ baba mi sunmọ-etile; nigbana li emi o pa Jakobu, arakunrin mi.
42 A si sọ ọ̀rọ Esau akọ́bi rẹ̀ wọnyi fun Rebeka: on si ranṣẹ o si pè Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo, o si wi fun u pe, Kiyesi i, Esau, arakunrin rẹ, ntù ara rẹ ninu niti rẹ lati pa ọ.