39 Isaaki baba rẹ̀ si dahùn o si wi fun u pe, Wõ, ibujoko rẹ yio jẹ ọrá ilẹ, ati ibi ìri ọrun lati oke wá;
40 Nipa idà rẹ ni iwọ o ma gbé, iwọ o si ma sìn arakunrin rẹ; yio si ṣe nigbati iwọ ba di alagbara tan, iwọ o já àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ.
41 Esau si korira Jakobu nitori ire ti baba rẹ̀ su fun u: Esau si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọjọ́ ọ̀fọ baba mi sunmọ-etile; nigbana li emi o pa Jakobu, arakunrin mi.
42 A si sọ ọ̀rọ Esau akọ́bi rẹ̀ wọnyi fun Rebeka: on si ranṣẹ o si pè Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo, o si wi fun u pe, Kiyesi i, Esau, arakunrin rẹ, ntù ara rẹ ninu niti rẹ lati pa ọ.
43 Njẹ nisisiyi ọmọ mi, gbọ́ ohùn mi; si dide, sá tọ̀ Labani arakunrin mi lọ si Harani;
44 Ki o si bá a joko ni ijọ́ melo kan, titi ibinu arakunrin rẹ yio fi tuka;
45 Titi inu arakunrin rẹ yio fi tutu si ọ, ti yio si fi gbagbe ohun ti o fi ṣe e: nigbana li emi o ranṣẹ mu ọ lati ibẹ̀ wá: ẽṣe ti emi o fi fẹ́ ẹnyin mejeji kù ni ijọ́ kanṣoṣo?