1 WỌNYI si ni iran Esau, ẹniti iṣe Edomu.
2 Esau fẹ́ awọn aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; Ada, ọmọbinrin Eloni, enia Hitti, ati Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, ara Hiffi;
3 Ati Baṣemati, ọmọbinrin Iṣmaeli, arabinrin Nebajotu.
4 Ada si bí Elifasi fun Esau; Baṣemati si bí Reueli;
5 Aholibama si bí Jeuṣi, ati Jaalamu, ati Kora: awọn wọnyi li ọmọkunrin Esau, ti a bí fun u ni ilẹ Kenaani.