34 Ẹ si mú arakunrin nyin abikẹhin nì tọ̀ mi wá: nigbana li emi o mọ̀ pe ẹnyin ki iṣe amí, bikoṣe olõtọ enia: emi o si fi arakunrin nyin lé nyin lọwọ, ẹnyin o si ma ṣòwo ni ilẹ yi.
35 O si ṣe, bi nwọn ti ndà àpo wọn, wò o, ìdi owo olukuluku wà ninu àpo rẹ̀: nigbati awọn ati baba wọn si ri ìdi owo wọnni, ẹ̀ru bà wọn.
36 Jakobu baba wọn si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin gbà li ọmọ: Josefu kò sí; Simeoni kò si sí; ẹ si nfẹ́ mú Benjamini lọ: lara mi ni gbogbo nkan wọnyi pọ̀ si.
37 Reubeni si wi fun baba rẹ̀ pe, Pa ọmọ mi mejeji bi emi kò ba mú u fun ọ wá: fi i lé mi lọwọ, emi o si mú u pada fun ọ wá.
38 On si wipe, Ọmọ mi ki yio bá nyin sọkalẹ lọ; nitori arakunrin rẹ̀ ti kú, on nikan li o si kù: bi ibi ba bá a li ọ̀na ti ẹnyin nlọ, nigbana li ẹnyin o fi ibinujẹ mú ewú mi lọ si isà-okú.