24 Ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na wá si ile Josefu, o si fun wọn li omi, nwọn si wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn; o si fun awọn kẹtẹkẹtẹ wọn li ohun jijẹ.
25 Nwọn si ti mú ọrẹ na silẹ dè atibọ̀ Josefu lọsán: nitori ti nwọn gbọ́ pe nwọn o jẹun nibẹ̀.
26 Nigbati Josefu si wọlé, nwọn si mú ọrẹ ti o wà li ọwọ́ wọn fun u wá sinu ile, nwọn si tẹriba fun u ni ilẹ.
27 On si bère alafia wọn, o si wipe, Alafia ki baba nyin wà, arugbo na ti ẹnyin wi? o wà lãye sibẹ̀?
28 Nwọn si dahun pe, Ara baba wa, iranṣẹ rẹ le, o wà sibẹ̀. Nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si bù ọlá fun u.
29 O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri Benjamini, aburo rẹ̀, ọmọ iya rẹ̀, o si wipe, Abikẹhin nyin na ti ẹnyin wi fun mi li eyi? o si wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe ojurere si ọ, ọmọ mi.
30 Josefu si yara; nitori ti inu yọ́ ọ si aburo rẹ̀: o wá ibi ti yio gbé sọkun; o si bọ́ si iyẹwu, o si sọkun nibẹ̀.