14 Josefu si kó gbogbo owo ti a ri ni ilẹ Egipti ati ni ilẹ Kenaani jọ, fun ọkà ti nwọn rà: Josefu si kó owo na wá si ile Farao.
15 Nigbati owo si tán ni ilẹ Egipti, ati ni ilẹ Kenaani, gbogbo awọn ara Egipti tọ̀ Josefu wá, nwọn si wipe, Fun wa li onjẹ: nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ? owo sa tán.
16 Josefu si wipe, Ẹ mú ẹran nyin wá, emi o si fun nyin li onjẹ dipò ẹran nyin, bi owo ba tán.
17 Nwọn si mú ẹran wọn tọ̀ Josefu wá: Josefu si fun wọn li onjẹ dipò ẹṣin, ati ọwọ́-ẹran, ati dipò ọwọ́-malu, ati kẹtẹkẹtẹ: o si fi onjẹ bọ́ wọn dipò gbogbo ẹran wọn li ọdún na.
18 Nigbati ọdún na si pari, nwọn si tọ̀ ọ wá li ọdún keji, nwọn si wi fun u pe, Awa ki yio pa a mọ́ lọdọ oluwa mi, bi a ti ná owo wa tán; ẹran-ọ̀sin si ti di ti oluwa mi; kò si sí nkan ti o kù li oju oluwa mi, bikoṣe ara wa, ati ilẹ wa:
19 Nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ, ati awa ati ilẹ wa? fi onjẹ rà wa ati ilẹ wa, ati awa ati ilẹ wa yio ma ṣe ẹrú Farao: ki o si fun wa ni irugbìn, ki awa ki o le yè, ki a má kú, ki ilẹ ki o má ṣe di ahoro.
20 Bẹ̃ni Josefu rà gbogbo ilẹ Egipti fun Farao; nitori olukuluku awọn ara Egipti li o tà oko rẹ̀, nitori ti ìyan na mú wọn: ilẹ si di ti Farao.