24 Yio si se, ni ikore ki ẹnyin ki o fi ida-marun fun Farao, ọ̀na mẹrin yio jẹ́ ti ara nyin fun irugbìn oko, ati fun onjẹ nyin, ati fun awọn ara ile nyin, ati onjẹ fun awọn ọmọ nyin wẹrẹ.
25 Nwọn si wipe, Iwọ ti gbà ẹmi wa là: ki awa ki o ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi, awa o si ma ṣe ẹrú Farao.
26 Josefu si ṣe e ni ilana ni ilẹ Egipti titi di oni-oloni pe, Farao ni yio ma ní idamarun; bikoṣe ilẹ awọn alufa nikan ni kò di ti Farao.
27 Israeli si joko ni ilẹ Egipti, ni ilẹ Goṣeni; nwọn si ní iní nibẹ̀, nwọn bísi i, nwọn si rẹ̀ gidigidi.
28 Jakobu si wà li ọdún mẹtadilogun ni ilẹ Egipti; gbogbo ọjọ́ aiye Jakobu si jẹ́ ãdọjọ ọdún o di mẹta:
29 Akokò Israeli si sunmọ-etile ti yio kú: o si pè Josefu ọmọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bi emi ba ri ojurere li oju rẹ, jọ̃, fi ọwọ́ rẹ si abẹ itan mi, ki o si ṣe ãnu ati otitọ fun mi; emi bẹ̀ ọ, máṣe sin mi ni Egipti.
30 Ṣugbọn nigbati emi ba sùn pẹlu awọn baba mi, iwọ o gbe mi jade ni Egipti, ki o si sin mi ni iboji wọn. On si wipe, Emi o ṣe bi iwọ ti wi.