27 Israeli si joko ni ilẹ Egipti, ni ilẹ Goṣeni; nwọn si ní iní nibẹ̀, nwọn bísi i, nwọn si rẹ̀ gidigidi.
28 Jakobu si wà li ọdún mẹtadilogun ni ilẹ Egipti; gbogbo ọjọ́ aiye Jakobu si jẹ́ ãdọjọ ọdún o di mẹta:
29 Akokò Israeli si sunmọ-etile ti yio kú: o si pè Josefu ọmọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bi emi ba ri ojurere li oju rẹ, jọ̃, fi ọwọ́ rẹ si abẹ itan mi, ki o si ṣe ãnu ati otitọ fun mi; emi bẹ̀ ọ, máṣe sin mi ni Egipti.
30 Ṣugbọn nigbati emi ba sùn pẹlu awọn baba mi, iwọ o gbe mi jade ni Egipti, ki o si sin mi ni iboji wọn. On si wipe, Emi o ṣe bi iwọ ti wi.
31 O si wipe, Bura fun mi. On si bura fun u. Israeli si tẹriba lori akete.