6 Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ ti iwọ bí lẹhin wọn ni yio ṣe tirẹ, a o si ma pè wọn li orukọ awọn arakunrin wọn ni ilẹ iní wọn.
7 Ati emi, nigbati mo ti Paddani wá, Rakeli kú lọwọ mi ni ilẹ Kenaani li ọ̀na, nigbati o kù diẹ ti a ba fi dé Efrati: emi si sin i nibẹ̀ li ọ̀na Efrati (eyi na ni Betlehemu).
8 Israeli si wò awọn ọmọ Josefu, o si bère pe, Tani wọnyi?
9 Josefu wi fun baba rẹ̀ pe, Awọn ọmọ mi ni, ti Ọlọrun fifun mi nihinyi. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mú wọn wá sọdọ mi, emi o si sure fun wọn.
10 Njẹ oju Israeli ṣú baìbai nitori ogbó, kò le riran. On si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀: o si fi ẹnu kò wọn li ẹnu, o si gbá wọn mọra.
11 Israeli si wi fun Josefu pe, Emi kò dába ati ri oju rẹ mọ́: si kiyesi i, Ọlọrun si fi irú-ọmọ rẹ hàn mi pẹlu.
12 Josefu si mú wọn kuro li ẽkun rẹ̀, o si tẹriba, o dà oju rẹ̀ bolẹ.