16 Jade kuro ninu ọkọ̀, iwọ, ati aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn aya ọmọ rẹ pẹlu rẹ.
17 Mu ohun alãye gbogbo ti o wà pẹlu rẹ jade pẹlu rẹ, ninu ẹdá gbogbo, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ; ki nwọn ki o le ma gbá yìn lori ilẹ, ki nwọn bí si i, ki nwọn si ma rẹ̀ si i lori ilẹ.
18 Noa si jade, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati awọn aya ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀;
19 Gbogbo ẹranko, gbogbo ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ gbogbo, ati ohunkohun ti nrakò lori ilẹ, gẹgẹ bi irú ti wọn, nwọn jade ninu ọkọ̀.
20 Noa si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA; o si mu ninu ẹranko mimọ́ gbogbo, ati ninu ẹiyẹ mimọ́ gbogbo, o si rú ẹbọ-ọrẹ sisun lori pẹpẹ na.
21 OLUWA si gbọ́ õrun didùn; OLUWA si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ki yio si tun fi ilẹ ré nitori enia mọ́; nitori ìro ọkàn enia ibi ni lati ìgba ewe rẹ̀ wá; bẹ̃li emi ki yio tun kọlù ohun alãye gbogbo mọ́ bi mo ti ṣe.
22 Niwọ̀n ìgba ti aiye yio wà, ìgba irugbìn, ati ìgba ikore, ìgba otutu ati oru, ìgba ẹ̃run on òjo, ati ọsán ati oru, ki yio dẹkun.