1. A. Ọba 20:25-31 YCE

25 Ki o si kà iye ogun fun ara rẹ gẹgẹ bi ogun ti o ti fọ́, ẹṣin fun ẹṣin, ati kẹkẹ́ fun kẹkẹ́: awa o si ba wọn jà ni pẹ̀tẹlẹ, nitõtọ awa o li agbara jù wọn lọ. O si fi eti si ohùn wọn, o si ṣe bẹ̃.

26 O si ṣe li amọdun, ni Benhadadi kà iye awọn ara Siria, nwọn si goke lọ si Afeki, lati bá Israeli jagun.

27 A si ka iye awọn ọmọ Israeli, nwọn si pese onjẹ, nwọn si lọ ipade wọn: awọn ọmọ Israeli si dó niwaju wọn gẹgẹ bi agbo ọmọ ewurẹ kekere meji: ṣugbọn awọn ara Siria kún ilẹ na.

28 Enia Ọlọrun kan si wá, o si sọ fun ọba Israeli, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nitoriti awọn ara Siria wipe, Oluwa, Ọlọrun oke ni, ṣugbọn on kì iṣe Ọlọrun afonifoji, nitorina emi o fi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia yi le ọ lọwọ́, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.

29 Nwọn si dó, ekini tì ekeji ni ijọ meje. O si ṣe, li ọjọ keje, nwọn padegun, awọn ọmọ Israeli si pa ọkẹ marun ẹlẹsẹ̀ ninu awọn ara Siria li ọjọ kan.

30 Sugbọn awọn iyokù salọ si Afeki, sinu ilu; odi si wolu ẹgbamẹtala-le-ẹgbẹrun ninu awọn enia ti o kù. Benhadadi si sa lọ, o si wá sinu ilu lati iyẹwu de iyẹwu.

31 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Kiyesi i, nisisiyi, awa ti gbọ́ pe, awọn ọba ile Israeli, alãnu ọba ni nwọn: mo bẹ ọ, jẹ ki awa ki o fi aṣọ-ọ̀fọ si ẹgbẹ wa, ati ijará yi ori wa ka, ki a si jade tọ̀ ọba Israeli lọ: bọya on o gba ẹmi rẹ là.