27 Ati ohunkohun ti o ba si nrìn lori ẽkanna rẹ̀, ninu gbogbo onirũru ẹranko, ti nfi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rìn, alaimọ́ ni nwọn fun nyin: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
28 Ẹniti o ba si rù okú wọn ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: alaimọ́ ni nwọn fun nyin.
29 Wọnyi ni yio si jasi alaimọ́ fun nyin ninu ohun ti nrakò lori ilẹ; ase, ati eku, ati awun nipa irú rẹ̀.
30 Ati ọmọ̃le, ati ahanhan, ati alãmu, ati agiliti, ati agẹmọ.
31 Wọnyi li alaimọ́ fun nyin ninu gbogbo ohun ti nrakò: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
32 Ati lara ohunkohun ti okú wọn ba ṣubulù, ki o jasi alaimọ́; ibaṣe ohun èlo-igi, tabi aṣọ, tabi awọ, tabi àpo, ohunèlo ti o wù ki o ṣe, ninu eyiti a nṣe iṣẹ kan, a kò gbọdọ má fi bọ̀ inu omi, on o si jasi alaimọ́ titi di aṣalẹ; bẹ̃li a o si sọ ọ di mimọ́.
33 Ati gbogbo ohunèlo amọ̀, ninu eyiti ọkan ninu okú nwọn ba bọ́ si, ohunkohun ti o wù ki o wà ninu rẹ̀ yio di alaimọ́, ki ẹnyin ki o si fọ́ ọ.