14 Ṣugbọn ni ijọ́ ti õju na ba hàn ninu rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́.
15 Ki alufa ki o wò õju na, ki o si pè e li alaimọ́: nitoripe aimọ́ li õju: ẹ̀tẹ ni.
16 Tabi bi õju na ba yipada, ti o si di funfun, ki o si tọ̀ alufa wá,
17 Alufa yio si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba di funfun, nigbana ni ki alufa ki o pè àlarun na ni mimọ́: mimọ́ li on.
18 Ara pẹlu, ninu eyi, ani li awọ ara ti õwo ti sọ, ti o si jiná,
19 Ati ni apá õwo na bi iwú funfun ba mbẹ nibẹ̀, tabi àmi didán, funfun ti o si ṣe bi ẹni pọ́n ki a si fi i hàn alufa;
20 Alufa yio wò o, si kiyesi i, li oju rẹ̀ bi o ba jìn jù awọ ara lọ, ti irun rẹ̀ si di funfun, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu õwo na.