3 Ẹnikẹni ti iṣe enia ile Israeli, ti o ba pa akọmalu tabi ọdọ-agutan, tabi ewurẹ, ninu ibudó, tabi ti o pa a lẹhin ibudó,
4 Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u li ẹbọ wi OLUWA niwaju agọ́ OLUWA: a o kà ẹ̀jẹ si ọkunrin na lọrùn, o ta ẹ̀jẹ silẹ; ọkunrin na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀:
5 Nitori idí eyi pe, ki awọn ọmọ Israeli ki o le ma mú ẹbọ wọn wá, ti nwọn ru ni oko gbangba, ani ki nwọn ki o le mú u tọ̀ OLUWA wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, sọdọ alufa, ki o si ru wọn li ẹbọ alafia si OLUWA.
6 Ki alufa ki o si bù ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si sun ọrá na fun õrùn didún si OLUWA.
7 Ki nwọn ki o má si ṣe ru ẹbọ wọn si obukọ mọ́, ti nwọn ti ntọ̀ lẹhin ṣe àgbere. Eyi ni yio ma ṣe ìlana lailai fun wọn ni iran-iran wọn.
8 Ki iwọ ki o si wi fun wọn, Ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti o ru ẹbọ sisun tabi ẹbọ kan,
9 Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u si OLUWA; ani ọkunrin na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.