7 Ki nwọn ki o má si ṣe ru ẹbọ wọn si obukọ mọ́, ti nwọn ti ntọ̀ lẹhin ṣe àgbere. Eyi ni yio ma ṣe ìlana lailai fun wọn ni iran-iran wọn.
8 Ki iwọ ki o si wi fun wọn, Ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti o ru ẹbọ sisun tabi ẹbọ kan,
9 Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u si OLUWA; ani ọkunrin na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
10 Ati ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti o ba jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ; ani emi o kọ oju mi si ọkàn na ti o jẹ ẹ̀jẹ, emi o si ke e kuro ninu awọn enia rẹ̀.
11 Nitoripe ẹmi ara mbẹ ninu ẹ̀jẹ: emi si ti fi i fun nyin lati ma fi ṣètutu fun ọkàn nyin lori pẹpẹ nì: nitoripe ẹ̀jẹ ni iṣe ètutu fun ọkàn.
12 Nitorina ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọkàn kan ninu nyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ, bẹ̃li alejò kan ti nṣe atipo ninu nyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ.
13 Ati ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti nṣe ọdẹ ti o si mú ẹranko tabi ẹiyẹ ti a ba jẹ; ani ki o ro ẹ̀jẹ rẹ̀ dànu, ki o si fi erupẹ bò o.