2 Ẹ kaye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, olukuluku ọkunrin, nipa ori wọn;
3 Lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli, iwọ ati Aaroni ni ki o kaye wọn gẹgẹ bi ogun wọn.
4 Ki ọkunrin kọkan lati inu olukuluku ẹ̀ya ki o si wà pẹlu nyin; ki olukuluku jẹ́ olori ile awọn baba rẹ̀.
5 Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin na ti yio duro pẹlu nyin: ti Reubeni; Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
6 Ti Simeoni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.
7 Ti Juda; Naṣoni ọmọ Amminadabu.
8 Ti Issakari; Netaneli ọmọ Suari.