23 Nwọn si dé odò Eṣkolu, nwọn si rẹ́ ọwọ́ àjara kan, ti on ti ìdi eso-àjara kan lati ibẹ̀ wá, awọn enia meji si fi ọpá rù u; nwọn si mú ninu eso-pomegranate, ati ti ọpọtọ́ wá.
24 Nwọn si sọ ibẹ̀ na ni odò Eṣkolu, nitori ìdi-eso ti awọn ọmọ Israeli rẹ́ lati ibẹ̀ wá.
25 Nwọn si pada ni rirìn ilẹ na wò lẹhin ogoji ọjọ́.
26 Nwọn si lọ nwọn tọ̀ Mose wá, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ni ijù Parani, ni Kadeṣi; nwọn si mú ọ̀rọ pada tọ̀ wọn wá, ati gbogbo ijọ, nwọn si fi eso ilẹ na hàn wọn.
27 Nwọn si rò fun u, nwọn si wipe, Awa dé ilẹ na nibiti iwọ gbé rán wa lọ, nitõtọ li o nṣàn fun warà ati fun oyin; eyi si li eso rẹ̀.
28 Ṣugbọn alagbara ni awọn enia ti ngbé inu ilẹ na, ilu olodi si ni ilu wọn, nwọn tobi gidigidi: ati pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀.
29 Awọn ara Amaleki si ngbé ilẹ ìha gusù: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ngbé ori-òke: awọn ara Kenaani si ngbé ẹba okun, ati ni àgbegbe Jordani.