39 Mose si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli: awọn enia na si kãnu gidigidi.
40 Nwọn si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si gùn ori òke nì lọ, wipe, Kiyesi i, awa niyi, awa o si gòke lọ si ibiti OLUWA ti ṣe ileri: nitoripe awa ti ṣẹ̀.
41 Mose si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nre aṣẹ OLUWA kọja? kì yio sa gbè nyin.
42 Ẹ máṣe gòke lọ, nitoriti OLUWA kò sí lãrin nyin, ki a má ba lù nyin bolẹ niwaju awọn ọtá nyin.
43 Nitoriti awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani mbẹ niwaju nyin, ẹnyin o si ti ipa idà ṣubu: nitoriti ẹnyin ti yipada kuro lẹhin OLUWA, nitorina OLUWA ki yio si pẹlu nyin.
44 Ṣugbọn nwọn fi igberaga gòke lọ sori òke na: ṣugbọn apoti ẹrí OLUWA, ati Mose, kò jade kuro ni ibudò.
45 Nigbana li awọn ara Amaleki sọkalẹ wá, ati awọn ara Kenaani ti ngbé ori-òke na, nwọn si kọlù wọn nwọn si ṣẹ́ wọn titi dé Horma.