16 Bẹ̃li o si ri nigbagbogbo: awọsanma bò o, ati oye iná li oru.
17 Nigbati awọsanma ba ká soke kuro lori agọ́ na, lẹhin na awọn ọmọ Israeli a si ṣí: nibiti awọsanma ba si duro, nibẹ̀ li awọn ọmọ Israeli idó si.
18 Nipa aṣẹ OLUWA awọn ọmọ Israeli a ṣí, nipa aṣẹ OLUWA nwọn a si dó: ni gbogbo ọjọ́ ti awọsanma ba simi lori agọ́ na, nwọn a dó.
19 Nigbati awọsanma ba si pẹ li ọjọ́ pupọ̀ lori agọ́ na, awọn ọmọ Israeli a si ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, nwọn ki si iṣi.
20 Nigba miran awọsanma a wà li ọjọ́ diẹ lori agọ́ na; nigbana gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a dó, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a si ṣí.
21 Nigba miran awọsanma a duro lati alẹ titi di owurọ̀; nigbati awọsanma si ṣí soke li owurọ̀, nwọn a ṣí: iba ṣe li ọsán tabi li oru, ti awọsanma ba ká soke, nwọn a ṣí.
22 Bi ijọ́ meji ni, tabi oṣù kan, tabi ọdún kan, ti awọsanma ba pẹ lori agọ́ na, ti o simi lé e, awọn ọmọ Israeli a dó, nwọn ki si iṣí: ṣugbọn nigbati o ba ká soke, nwọn a ṣí.