3 Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé “Mo sọ ọ́ di mímọ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba wa.”
4 Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ.
5 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Árámíà, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Éjíbítì pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀ èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.
6 Ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá níyà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe.
7 Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa.
8 Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Éjíbítì pẹ̀lu ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu.
9 Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin;