15 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú àrùn gbogbo, kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí àrùn búburú tí ẹ mọ̀ ní Éjíbítì wá sára yín, ṣùgbọ́n yóò fi wọ́n lé ara gbogbo àwọn tí ó kórìíra yín.
16 Gbogbo àwọn ènìyàn tí Olúwa Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátapáta. Ẹ má ṣe sàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín.
17 Ẹ lè máa rò láàrin ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀ èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?”
18 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn: Ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Fáráò àti gbogbo Éjíbítì.
19 Ẹ sáà fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. Olúwa Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù.
20 Pẹ̀lúpẹ̀lù, Olúwa Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrin wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sápamọ́ fún un yín, yóò fí ṣègbé.
21 Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀.