35 Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì run àádọ́tàlénígba ọkùnrin (250) tí wọ́n mú tùràrí wá.
36 Olúwa sọ fún Mósè pé,
37 “Sọ fún Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà, pé kí ó mú àwọn àwo tùràrí jáde kúrò nínú iná nítorí pé wọ́n jẹ́ mímọ́, kí ó sì tan iná náà káàkiri síbi tó jìnnà.
38 Èyí ni àwo tùràrí àwọn tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kí ẹ gún àwo tùràrí yìí, kí ẹ sì fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ, wọ́n jẹ́ mímọ́ nítorí pé wọ́n ti mú wọn wá ṣíwájú Olúwa. Kí wọ́n jẹ́ àmì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”
39 Élíásárì tí í ṣe àlùfáà sì kó gbogbo àwo tùràrí tí àwọn tí ó jóná mú wa, ó gún wọn pọ̀, ó fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ,
40 Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe sọ láti ẹnu Mósè. Èyí yóò jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ẹlòmíràn yàtọ̀ sí irú ọmọ Árónì kò gbọdọ̀ jó tùràrí níwájú Olúwa, ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò dàbí Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
41 Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ ènìyàn kùn sí Mósè àti Árónì pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn Olúwa.”